2 Chronicles 9:22-27

22Ọba Solomoni sì tóbi nínú ọláńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ. 23Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojúrere lọ́dọ̀ Solomoni láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀. 24Ní ọdọọdún, olúkúlùkù ẹni tí o wá mú ẹ̀bùn ohun èlò wúrà àti fàdákà àti aṣọ ìbora, ìhámọ́ra, àti tùràrí, àti ẹṣin àti ìbáaka wá.

25Solomoni sì ní ẹgbàajì ilé fún àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, àti ẹgbàafà àwọn ẹṣin, tí ó fi pamọ́ nínú ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ nínú Jerusalẹmu. 26Ó sì jẹ ọba lórí gbogbo àwọn ọba láti odò Eufurate títí dé ilé àwọn ará Filistini àti títí ó fi dé agbègbè ti Ejibiti. 27Ọba sì sọ fàdákà dàbí òkúta ní Jerusalẹmu, àti igi kedari ni ó sì ṣe bí igi sikamore, tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
Copyright information for YorBMYO